Jagun Jagun

Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀

Olórí-ogun ò gbọdọ̀ kẹ́yìn ogun
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹja tí ń d'abú-omi rú
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹfọ̀n tí ń d'ọ̀dàn rú
Ọ̀kan ṣoṣo Àjànàkú tí ń m'igbó kìji-kìji
Jagun-jagun dé, ọmọ ọba kìí jagun bí ẹrú
Òlọ́ṣọmọ́dìí gba ìbọn lọ́wọ́ ọmọ ojo
Jagun-jagun, afiwájúgbọta, afẹ̀yìngbọfà
Jagun-jagun ò fẹ́rọ̀, alágbára èyàn tí ń fi májèlé ròfọ́
Àlùjànú èyàn tí ń fi ọmọ-odó tayín
Bó ṣe ń bá ọmọdé ṣe, bẹ́ẹ̀ ló ń bágbà ṣe
Kọ̀nàn-kọ̀nàn já tòun tòwú
Jagun-aso, ẹkùn ọkọ òkè!
Arọnimaja ṣáagun!
Ó ṣáagun ṣáagun, ó ṣáagun títí
Ohun l'awo Alágbàá'a, èyí tí ó fi ta b'aṣeégún lójú

Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀



Credits
Writer(s): Abiodun Oke, Adegoke Odukoya, Akin Akinhanmi, Akinkunmi Olagunju, Ayomiku Aigbokhan, Babajide Okegbenro, Damilola Williams, Dare Odede, Ibrahim Oyetunji, Isaiah Odeyale, Laolu Ajibade, Olufemi Sanni, Opeyemi Oyewande, Peter Sadibo
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link