Gba Isakoso

Pipele,Pipele lo n pele o
Pipele,Pipele lo n pele o
Pipele,Pipele lo n pele ooo
Pipele,Pipele lo n pele o
Kaka k'ewe agbon de
Pipele lo n pele
Kaka k'oro iya aje,
O fi gbogbo omo re b'obirin
Kaka k'ewe agbon de
Pipele, Pipele lo n pele o

Pipele,Pipele lo n pele o
Pipele,Pipele lo n pele o
Pipele,Pipele lo n pele ooo
Pipele,Pipele lo n pele o
Kaka k'ewe agbon de
Pipele lo n pele
Kaka k'oro iya aje,
O fi gbogbo omo re b'obirin
Kaka k'ewe agbon de
Pipele, Pipele lo n pele o

Ye, Oluorun o
Dide wa ran wa l'owo o
Gbo ohun ebe wa, ni Naijiria yi o
Olododo o si mo, won s'aye di je ki n je
Igunnugun yan ni je, Akala yan ni je, o lo o
Ye, Oluorun, Eledumare, wa ko wa yo

A n be o, Oluwa, dide ko gba Isakoso
Yi igba buburu pada si rere fun wa
Ounje to won, so won d'opo fun wa
Mekunnu n jiya, Eledumare wa ko wa yo
Rogbodiyan ile aye yi papoju, la se ke si o o
Lai si ese, ijiya o si o, Eledumare wa darijini

Pipele,Pipele lo n pele o e
Pipele,Pipele lo n pele o
Pipele,Pipele lo n pele si i, lojojumo o
Pipele,Pipele lo n pele o
Kaka k'ewe agbon de
Pipele lo n pele
Kaka k'oro iya aje, o fi gbogbo omo re b'obirin
Kaka k'ewe agbon de
Pipele, Pipele lo n pele o

L'aye ojosi, b'omo ba ka iwe mefa
Bi eni ka gbogbo iwe ni o o
Iwe kika jo'ju, laye ojosi, b'omo ba ka iwe mefa
Bi eni ka gbogbo iwe ni e e
Sugbon l'ode oni o, aye ti d'obiripo
Omo re Yunifasiti, o ri bi eni re je'le-osinmi
Omo ka gbogbo iwe tan
O wa se, wa se o, ko ma ri 'se fi se
Ki l'anfaani Satifike t'a gba ta o ri 'se fi se
Ki l'afaani ile iwe t'a lo, t'a jade ti a o ri'se
Ebe la be yin, eyin ijoba
E ba wa, w'ono abayo, tori
Owo to ba di'le, l'esu n ran ni'se, eyi l'adigunjale fi po o

Iwa ibaje lorisirisi, ojoojumo lo n gbile si
Ka maa pa'ra wa, bi eni p'eran
Ko ti le, jo wa l'ojumo
419 lorisirisi, iwa ibaje d'oun a mu s'oge
Awa n be o Eledua, Baba, ma se wo wa ni'ran
Tete je ki'joba re de, k'a se bere lori ase'bi
Ki'na Orun sokale wa o, ko jo gbogbo imo esu run
Ki iya to n je Olododo, ko le d'oun igbagbe o

Ko le d'oun igbagbe o
Ko le d'oun ari'pitan
Ko le d'oun igbagbe o
Ko le d'oun amu'pitan
Si'ju aanu re wo wa o
Edumare wa tun Naijiria yi se

Si'ju aanu re wo wa se
Edumare wa tun Naijiria yi se
Orileede yi n fe atunse
Edumare wa tun Naijiria yi se
A ti f'otito pamo, iro nikan la n pon o
Edumare wa tun Naijiria yi se
A f'oun to ye sile, ase'yi ti ko ye
Edumare wa tun Naijiria yi se
Ah! Oba Edumare dakun gba wa o
Edumare wa tun Naijiria yi se
Ninu rogbodiyan ile aye yi
Edumare wa tun Naijiria yi se
Omo ka iwe tan, e mo ri'se fi se
Edumare wa tun Naijiria yi se
Eni n s'ise da bi ole o
Edumare wa tun Naijiria yi se
Igbe ole loni, igbe ole lola
Edumare wa tun Naijiria yi se
419 lorisirisi
Edumare wa tun Naijiria yi se
Bee, ita'jesi'le l'o'lokanojokan
Edumare wa tun Naijiria yi se
A wa da bi agutan ti ko l'oluso o
Edumare wa tun Naijiria yi se
Ki iya to n je Olododo, k'o le d'oun igbagbe o

Ko le d'oun igbagbe o
Ko mo le d'oun ari'pitan
Ko le d'oun igbagbe o
Ko le d'oun amu'pitan
Si'ju aanu re Baba o
Edumare wa tun Naijiria yi se

Jowo dakun Baba si'ju aanu re wo wa
Edumare wa tun Naijiria yi se
Gbogbo wa n w'odo b'ose n gbe'gi Arere lo o
Edumare wa tun Naijiria yi se
Igba ti Odo n gba'rere lo o
Edumare wa tun Naijiria yi se
Ba wo ni, Ba wo ni, t'Araba yo se ri
Edumare wa tun Naijiria yi se
Ba wo l'eyin ola awon omo wa yo se ri
Edumare wa tun Naijiria yi se
Ebi ti so'po eniyan d'alarinkiri
Edumare wa tun Naijiria yi se
Won n se "Bambi Allah" ki won to jeun
Edumare wa tun Naijiria yi se
Won n se "Bambi Allah" e bun mi nitori Oloun Oba o
Edumare wa tun Naijiria yi se
Asita ibon n d'emi awon eyan l'egbodo o
Edumare wa tun Naijiria yi se
Awon agbesunmomi n fooro emi wa
Edumare wa tun Naijiria yi se
Let the killings stop! Let the violence cease!
Edumare wa tun Naijiria yi se
T'oba je t'ese, Baba darijini
Edumare wa tun Naijiria yi se
F'orjiwa dakun, s'aanu fun wa o
Edumare wa tun Naijiria yi se
T'oba je t'ese, Baba a be o
Edumare wa tun Naijiria yi se

Edumare, Edumare, Edumare
Edumare o

Ki iya to n je Olododo, k'o le d'oun igbagbe o



Credits
Writer(s): Bukunmi Babarinsa
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link