Moriamo

Ọmọ Adefi
Ọmọ Adefa lókè Iresi
(Moriamo Alege) (Moriamo)

Ìyá bàbá mí, sún re
Ní ilé àyé, 1980 something
(The Beat Handle)
Damilare, èmi l'àkọ́bí bàa mi, kí Qudus tó dì Qdot
Ìyá àti bàbá mí tí Jáà ó tí pẹ
Kí n tó wa'yé l'ọn tí ní wọn le fẹ'ra wọn
Okun ẹbí to ba Jáà, welder kàn ó lé jo (Alagbe)

K'Ọlọrun f'ọrun kẹ Moriamo, ìyá bàbá mí
Moriamo, ọmọ Alege
Ìyá má ń gb'ọmọ gẹ-gẹ ní
Màmá ó gbé mí sílẹ̀ k'èyàn kan-kan tọju mí
Moriamo, ọrun re
Mí ó gbàgbé okò Alado o, l'ọnà Erugbabu
Okò obi yí grandma tí fọ lójú kàn
Bó yà ń torí obi tó mà tá ní muri kàn

Ìyá yí tún padà s'oko, ada, t'oun t'ọkọ ní
Orí mí à wú to bà pé mí lọkọ mí
Ọjọ rí jẹ, pẹlú ọjọ rírí mú
Màmá ma ń ro'ka pẹlú ẹfọ Bọkọlu

Omi odò là má ń mú (omi odò là má ń mú)
Labúlé Ado, labúlé Ado oh
(Abúlé Ado) abúlé wá ó jìnà si Shagamu
À ń padà s'oko ní motor jamu (ó má ṣée)
Màmá bà ń pariwo, "Damilare, ọmọlọmọ ní, ẹ bà ń gbé"
Ó mà ṣeé, ó mà ṣee (ó mà ṣeé)
Ọjọ yẹn ní mo mọ pé ìyá yí kọ lo bí mí

Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege (Moria oh)
Moriamo Alege, ìyá bàbá mí, ọrun re rẹ

Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege (Moria oh)
Moriamo Alege
Ìyá bàbá mí, ọrun rè rẹ (Moriamo)
Ọrun re rẹ (Moria oh)

Hmm, ọjọ re bí ana nígbà t'ikú wọlé dé
Ìyá yí tí r'ikú ló ṣe ní ń b'ode lọ
K'ojú mí mà bà r'ibi
Rafiu, àbúrò mí ń gbà bọọlu nítá
Mo wọlé padà, màmá tí d'ojú bo'lẹ

Kàyéfì ló jẹ, mo sáré pé bàbá mí
Adio, ó bà dákún, wá wó màmá rẹ
À ṣé ọlọjọ lódé o
Ń gbà t'ariwo tá, l'ọn bí wà, "Kí ló dé?"
Kí n to mọ, ẹsẹ tí pé
Shifau, pẹlú Mutairu béèrè sí ń ké (omijé oh)

Wọn ní wọn ó le sìn màmá
Mo ni, "Kí ló dé?"
Wọn ní, "Ẹmí ó jáde tán" (ahh)
Kò fẹ f imí silẹ lọ ní
Ọjọ ìkíni lọ, ìkejì lọ
Ọjọ ìkẹta, Moria dágbere fún ayé

Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege (Moria oh)
Moriamo Alege
Ìyá bàbá mí, ọrun re rẹ

Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege (Moriamo)
Moriamo Alege
Ìyá bàbá mí, ọrun re rẹ (Moriamo)
Ọrun re rẹ (Moriamo oh)

Moria dàgbere fún ayé
Odi'gbà, odi gbere (Moriamo)
Mama Shifau, Mama Mutairu
Moriamo, ọmọ Alege, ọrun re rẹ

Mà ro'yin ẹ f'ọmọ mí (Moriamo oh)
Moriamo (Moriamo), Moriamo oh
Moriamo (Moriamo)
Moriamo Alege

(Yeah, who's here?)



Credits
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link