The Horse, The Man & The Son

Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o
... (Interlude)

L'ojo t'aba bi 'mo tuntun si ile aye
t'onille t' alejo lo ma ki ni kuu ewu
Ota omode bere lati ni bi irakoro
Ka da ni l'ojeun nu, oti bere ota nini
Ka da ni l'omi nu, oti bere ota nini
O ti bo so owo aye
... (Interlude)

T'omo naa ba ti bere si ni rin
To ba l'egbe to n jo sere, l'aarin adugbo
Ti obi re ba le ra keke fun,
O ti bo so owo aye
To ba ni ko gbe wa, ko jo fi sere
To ba ni rara, oti d'ota won
O ti bo so owo aye
Won ani ma gbe keke e lo
A'o ba e sere mo.
... (Interlude)

Ti ojo ba g'ori ojo, ti omo naa ba d'agba
To bere si ni re ile iwe, to f'oju si eko rẹ, to n se dede
Ti wo n ba se idanwo, to ba se ipo kinii
O ti di ota on'ipo k'efa, won fun l'oruko
Won ni omo teacher ni
... (Interlude)

A s'eyin wa a s'eyin bo, omo 'jo si bere ise
Oga ile ise ni ko ma de b'ise ni agogo mejo
O n se dede, o de b'ise ni akoko, kii pa t' ise je
Awon ole afajo, won fun loruko
Won ni omo manager ni
O ti bo s'owo aye
... (Interlude)

Omo to ba n sise dede, o ye ko ni asiko igbadun
Igba ti o fi j'aye.

To ba lo si party nibi ti won je igbadun,
to ba ni ki loo mu, lo ba ni Coca-Cola, won ni jedi-jedi lo ma pa.
To ba lo si party nibi ti won je igbadun,
to ba ni ki loo mu, lo ba ni Coca-Cola, won ni jedi-jedi lo ma pa.
... (Interlude)

To ba tun je oga oni faaji, to n j'aye dede
Champagne pelu schnapps, ti o fi n yonu
Heineken beer, Star lager, Top beer
Becks beer pelu Guinness, gbogbo re l'oba l'ara mu
Awon eda Adamo, won fun l'oruko
Oti l'alakori f'owo re mu
... (Interlude)

To ba tun wa lo je, agba man, to lo aso asiko
To tu l'ori obinrin, won fun l'oruko
Igberaga ti p'oju, ko mo ju obinrin lo, Sina l'arakori f'owo e se
... (Interlude)

To ba tun je oni suru, to ka iwe to gb'oye repete
To n d'ogbon jaye, ti ki s'aapon, ti ko feran obirin
Awon eda Adamo, won fun l'oruko
Alakori akada ni se lo n roju koikoi
... (Interlude)

Omu mi ranti, itan baba kan pelu omo re ti won sin ketekete
Omu mi ranti, itan baba kan pelu omo re ti won sin ketekete
Eshin pelu ketekete, o da bi motor to won gun lo s'ode
Eshin pelu ketekete l'aye ojo yen, o da bi motor ti won gun lo s'ode

Ketekete ti d'agba, baba pelu omo e ba mura ode, won fe r'irin ajo kan
Gege bi agbalagba, baba gun ketekete, omo re rin tele lo
Bi won se rin s'iwaju die, won pade Adamo, eda omo araye
Omo araye ni Ow! Baba agbalagba omo re n'ile, iwo n gun ketekete

Baba ba bo s'ile lori ketekete, l'oba gbé omo re s'ori ketekete
Won ba mu irin ajo won pon,
Won lo! Won lo!!
Bi won se rin s'iwaju die, won tun pade Adamo, eda omo araye
Omo araye tu ni Ow!
Baba omugo, o rin n'ile, omo gun ketekete

Baba ba tun sure, o gb'omo s'ile,
O sare gun ketekete, o tun gb'omo s ori ketekete
Eni meji-reji lori ketekete
Won mu irin ajo wo pon
Won lo! Won lo!!

Bi won se tu rin s'iwaju die, won pade Adamo, eda omo araye
Omo araye tu ni Ow!
Omo ati baba, alaini anu ni yin,
Eyin mejeji lori ketekete, e fe pa ketekete ni?
... (Interlude)

Baba ba w'oke titi,
Oni ma te yin l'orun, eyin eda omo araye
Baba ba gb'omo s'ile lori ketekete
Ohun naa bo s'ile lori ketekete.
Ketekete n lo l'ofo, baba pelu omo re won fi ese rin tele

Bi won se tu rin s'iwaju die, won pade Adamo, eda omo araye
Omo araye tu ni Ow!
Eyin mejeji, eru aye ni yin
E rin n'ile, ketekete n lo l'ofo

Baba pelu omo, re gege bi mo ti wi, won bo s'ile
Ketekete n lo niwaju, won fi ese rin tele
Won tun rin s'iwaju die, won pade Adamo, eda omo araye
Omo araye ni Ow!
Eyin mejeji, eru aye ni yin
E rin n'ile, ketekete n lo l'ofo

Baba ba b'oju woke, o fe ranti orin Chief Commander
Oni edakun e fe yi k'ogbon

Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o
Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o

... (Interlude)

Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o
Ko s'ogbon to le da, ko si wa to le wu
Ko si ona ti o le mo to le fi t'aye lorun o

Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o
Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o
A fi ka w'uwa rere, rere lo pe, omo araye e se re o
Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o
Commander Ebenezer, do your best and leave the rest .
... (Interlude)

Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o
Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o
Rere lo pe, a fi ka ma w'uwa rere, omo araye e se re o
Ile aye fun igba die ni o, omo araye e se re o



Credits
Writer(s): Ebenezer Olasupo Obey-fabiyi
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link