E Ho Iho Ayo

Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé.
Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA.
Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀.
Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun,
òun ló dá wa, òun ló ni wá;
àwa ni eniyan rẹ̀,
àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.
Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́,
kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn.
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀,
kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀.
Nítorí OLUWA ṣeun;
ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae,
òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.



Credits
Writer(s): Oluseun Akinwole
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link