Opin Irin Ajo (Remix)

Bi e ba n gbo t'omode n ge 'gi ni 'gbo
Agba lo le mo 'bi to mi a wo si
B'omode ba rin irin ajo loju agba
O le ma ba agba mo ni'le to ba de o
Irin ajo eda laye, Olorun lo mo
Opin irin ajo k'a fi s'adura
Opin irin ajo temi tire ninu aye
Oba je ko san wa o k'a jagunmolu

Ti e ba n gbo
Bi e ba n gbo t'omode n ge 'gi ni 'gbo
Agba lo le mo 'bi to mi a wo si
B'omode ba rin irin ajo loju agba
O le ma ba agba mo ni'le to ba de o
Irin ajo eda laye, Olorun lo mo
Opin irin ajo k'a fi s'adura
Opin irin ajo temi tire ninu aye
Oba je ko san wa o k'a jagunmolu

Opin irin ajo, oo— laye
Abalo, ababo wa ninu aye
Laisi laala ko ma si isinmi
Eni to maa yege o, a rin un wi
O fe lowo, o fe ko'le o ninu aye
Laisi 'ranwo Olorun ofo lo ma ja si
Eni fe se rere o, dandan a w'oju Olorun
Esu o ni fun o lookan, ko ma fi gb'eedegbaa
Ona eburu lonitohun yen a fi parun (a pa run ni)

Opin irin ajo temi tire ninu aye
Oba je ko san wa o, ka jagunmolu
Laala ninu aye, irin ajo aye
Ogun to n ja, t'Olorun nse won a re koja lo
Opin irin ajo ni'ku, a gbe ni ju langba si koto
Eni ti ku ni'sinmi, iyen p'orisirisi
Ibi ta o re, b'a d'orun lo ja ju o
Ibo lodo temi tire? Ore je ka roo
Oba je ko san wa o, ka b'Olorun nile

Opin irin ajo temi tire ninu aye
Oba je ko san wa o, ka jagunmolu

Jesu ti wa s'aye lati ku fun emi ati iwo, ore ma se ko ife Jesu yi o
Nitori o san fun eniyan lati ma wa'ye rara, ju pe k'o pada s'orun apaadi lo
Ore mi mo n be o, iku Jesu Kristi, mase je ko ja s'asan

Oniwakuwa ronu k'o lo ja'wo
Alagbere, oniwokuwo k'e ya so se
Ole, janduku, e ku ireti ojo idajo
K'aborisa ko pa un ti o soro ti k'o sin l'Ohun
E ye bo satani lowo k'e tun f'enu ko Jesu
S'eke, s'ajo ko s'eni t'o gb'alubosa, e gbo? To maa fi ka 'la o, iyen d'eewo

Opin irin ajo temi, tire ninu aye
Oba je ko san wa o, ka jagunmolu

Aye o ni 'boji, orun ni 'boji aye
Eni da 'mi siwaju lo n te 'le tutu
Eni lo s'ajo to mi a de ti o ti ferese
Iyen gbe 'se ile re f'onisona ko w'eyin wo rara
K'o to dele, iji ka'ja, ojo wole p'eru
Iboji a da ninu ile to ti d'aatan
Eni ye ko wole mu'mi sinmi a tun ko sise
Opin irin ajo, isinmi lo ye k'o je

Ti e ba n gbo
Bi e ba n gbo t'omode n ge 'gi ni 'gbo
Agba lo le mo 'bi to mi a wo si
B'omode ba rin irin ajo loju agba
O le ma ba agba mo ni'le to ba de o
Irin ajo eda laye, Olorun lo mo
Opin irin ajo k'a fi s'adura
Opin irin ajo temi tire ninu aye
Oba je ko san wa o k'a jagunmolu

Bi e ba n gbo t'omode n ge 'gi ni 'gbo
Agba lo le mo 'bi to mi a wo si
B'omode ba rin irin ajo loju agba
O le ma ba agba mo ni'le to ba de o
Irin ajo eda laye, Olorun lo mo
Opin irin ajo k'a fi s'adura
Opin irin ajo temi, tire ninu aye
Oba je ko san wa o k'a jagunmolu



Credits
Writer(s): Bioku Llc
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link