Imoran

Jerryson production

Iyawo timoko e lonimoran, oko iyawo tim'aya e lalashiri

Kesu mayawon karun mayawon
Kiya majewon kondijo barawon gbepe

Iyawo timoko e lonimoran
Oko iyawo tim'aya e lalashiri

Kesu mayawon karun mayawon
Kiya majewon kondijo barawon gbe pepepe

Toripe
Iteriba se pataki kiyawo oni
F'ade ori e kosi tun ma bowo fun ni

Maroju kojo
Maroju koko
Maroju koko toko bansoro lowo

Je koju tutu kosi rin erin muse
Gbiyanju jeyawo toma nwu oko lori

Alubarika towa nibe oma kere
Kesu mayayin karun mayayin
Koshi katayin kedijo gbepo pepepe

Iyawo timoko e lonimoran
Oko iyawo timaya e lalashiri

Kesu mayawon karun mayawon
Kiya majewon kondijo b'arawon gbepe

MashaAllah
Idunnu aya loleto ki oko o wa
Taya ba roju ko mona tio gba tujuka

Ko f'oriki pe o, koni ashake o
Ko f'oriki pe kofeso wo'yawo mora
Peloju tutu atoro toro kowipe

Ife ayemi honey, idunnu mi darling
Iyawo mi kiloun tole fa'runju
Toba sepe mose e ni lonfa ibinu

Salaye funmi ifemi madimi sinu
Kodarijinmi o konisele mo lailai

Iyawo timoko e lonimoran
Oko iyawo tim'aya e lalashiri

Kesu mayawon karun mayawon
Kiya majewon kondijo b'arawon gbepe

Naam!
Toko bapase iyawo gbodo tele ni
Toba lo jeyi toti ro poun o ma lese

Kiyawo majiyan lesekese si rara
Leyin iseju die kosofun oko wipe

Ife okan mio
Oyin ayemi
Olowo orimi moma loro tinfewi

Oun teni kase ero kan wa sokan mini
Ebaje karo kato gbese si rara

Mo mope ooo a bere kilawon lese
Kori dajupe imoran tole fun tiwa
Oro naa apada wa doro ajoso ni

Iyawo timoko e lonimoran
Oko iyawo tim'aya e lalashiri

Kesu mayawon karun mayawon
Kiya majewon kondijo b'arawon gbepe

Oko iyawo wa teti gboro tinfewi
Teti beleje kole gboro mi yeke

Ati feyawo o ja bi okunrin o gbon
Mowa foniwa ni loko laya fingbe pe

Koma senikan tio nibi towosi
Ibi taya kusi koko o mofun loto

Ibi toko kusi, kiyawo o mofun loda
Kele jogbe dale o, kalafia le joba ni

Iyawo timoko e lonimoran
Oko iyawo tim'aya e lalashiri

K'esu mayawon karun mayawon
Kiya majewon kondijo b'arawon gbepe

Tor'oju orun funfun nene o labawon o
Eniyan se fe dara to koma nibi to wosi

Al'oju orun funfun nene o labawon o
Eniyan se fe dara to koma nibi to wosi

Enife jadun lara oyin oye komope
Eni to woyin rebi afara afoju wina o

Ise apo kato r'afara gbe wale wa
S'oyin to fadun se gbogbo ara t'oyin ba tani

Saowa lao ni layinmo aopada la o
Toko tiyawo mofe kamo pao serawa o

Leyin sorry eje kotan koma ku sinu o
Iwa to jowa loje konsope ore jore o

Tor'oju orun funfun nene o labawon o
Eniyan se fe dara to koma nibi to wosi

Eyan mi kan losoro kan funmi nigbakan
O nigba toun omai ti feyawo

Tawon bajowa pelawon ore to niyawo, telomiran baso nkan tiyawo e se

Tawon ba nforo jomitoro oun asope
Toun ba feyawo toba dan iru e wo

Oun a keru e komalo sile won ni
Oloun o mope aimokan nsoun nigbayen ni

O l'oun toti juyen lo niyawo oun se
Leyin kodija kawon tun pari e ni

Tor'oju orun funfun nene o labawon o
Eniyan se fe dara to koma nibi to wosi

Aimoye oko kiwon nseyawo won
Sebawon iyawo won pada mu mora ni

Won ni toko awon bati sawon lese kan, kanto bene inu atiro bee naa nio

Won ni tori ese gangan l'Olohun seda
Aforijin, kaye legun kole n'itura

Sale tori ese oko ka lao semo, angeli ko lama rife eyan naa ni

Won lawon atoko won timowo arawon, kosiru ese tasewon won mu mora ni

Won l'oju orun funfun nene o labawon o
Eniyan se fe dara to koma nibi to wosi

Asiko yi moti pinnu fun ife mi
Latibere tife tayo lafin barase

Ifemi ayomi oyin ayemi alashiri mi
O gba funmi mose tie denu dokan ni

Atijowa moti mo e latana doni o
Moti rie tan bosewa bami lara mu

Moti pinnu tan lokan mi pe kosi nkan
Tole yàwa k'olohun koma fiku yawa

K'esu bi eyan ton daleru mayale awa
Eniyan sefe dara to koma nibi to wosi

Ema delewa mo, ema wale wamo
Ija le lewa pari asero ni
Abosi lewase o kole gbeyin

Anpeyin leyan wa, otete mope, agabangebe lewase atiwa abosi

Ede aiyede lani tasi for loyin
Oro taso lowuro o koi dirole

Ninu adugbo latingbo ateyinkule
S'ese ni ka fiyinse eni anforo lo

Ija le lewa pari asero ni
Ofofo lewa se o kole gbeyin

Ao jamo ema wale kan ilekun mo
E pase funjalo ao foro loyin

Oju aye lewase ayonuso ni
Agborodun e japa ao fe riyin mo

Ema delewa mo, ema wale wamo
Ija le lewa pari asero ni
Abosi lewase kole gbeyin

Oya o dun o, ofe ke
O dun o, ofe ke

Untoiiin, ofe ke
Oro yen ba oo, ofe ke

A bujo, ofe ke
A fajo, ofe ke

O dun ooo, ofe ke
MashaAllah
MashaAllah



Credits
Writer(s): Oriyomi Kehinde Sanni
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link