Oruko Oluwa

Oluwa, oruko re ti Niyi to nigbogbo aye
Kabiosi o, Olorun ododo
Atobajaye, Gbanigbani tin koni yo
Agbanilagbatan, Akomati kaleyin
Alpha, Omega, ibere ati opin owun
gbogbo
Awuwo mashey gbe, onikan gberae nija
Kiniun eya juda, olori ariran
Omonamona ton shoju orun madomado
Gbengbeleku tin koni yo lojo Ogun
Alagbada ina, Alawotele orun
Adeda, aseda, aweda, ameda
Jagunjagun ode orun
Obirikiti ajipojo iku da
Obirikoto oba asorun dero
Oba to fina bora bi aso
Arugbo ojo, adagba ma paro oye
Adagba ma paro ipo, adagba malo gilassi, eleyin ju anu
Oba ogo, ogbamugbamu ojuorun oshey gbamu
Gbingbin niki alafin orun
Pro kankan tin ka satani laya,
iduro re oro, ijoko re oro
Oro tin gbe oro mi, oro gbe nu omo eniyan fohun
alagbara giga giga giga giga, ton gba agbara lowo alagbara to fi fii agbara ni omo alailagbara lara
arugbo igba ni, oba to ni igba ati akoko
Oba asekan maku, Oba Lana, Oba Loni, Oba lojo gbogbo
Kabi e osi ninu awon orun
adunbagbe, adunbarin ma to shii
ajadenile matan Nile, olumo ipinleshe ohun gbogbo
alade wura, alade ogo, alade ina
Oba to gun iji leshin, Oba to joko lori obiri aye
arogun masa, arogun mashojo
Ibi isadi onigbagbo, gbongbo idile jesse
agbenu orun mon ohun tin wan shey laye
Oloju ina, alawotele orun
Adajo agba tin wo angeli gbo gbo
Oluko agba, Olutoni to mona julo
Akoni mowi, Akonimose, baba mi agbalagba oye
Eleru Niyi, agbanilowo iku
agbanilowo arun, agbanilowo ese
Apata ayeraye, Okele gbangba tosho ati aje olemi
Oba ton do ba lade, Oba ton gbade lori oba
Oba mimo, ton shey mimo, ton je mimo, ton mu mimo, ton soo mimo, to joko nibi mimo
Irukere mimo, Opa ashey mimo, Adeori mimo, Agbada mimo
Mimo, mimo, alafunfun gbo kanle
Awi mayehun, aiku, Aisha, aileyipada, aidibaje, aiitetekoshey
akikitan, alaragbayida
apata rabata, afuni mashiregun, agbonmagbe ninu ola
adurotini lojo isoro
aponmo maweyin
apani, alani, ajini, agbeni, agbani, aleni, amuni, ashorekiri, olusegun, oluboriogun
olumoranokan, olutunnu, olubukun, olupese, olupamo, olugbeja, oludamoran
Oluwa, oluwawa, oruko re tiniyi to nigbogbo aye
aleni bani lona lai kuro loju kan soso
ekun oko oke

Olorun toda awon oke igba ni
eyin ni mo fi ope mifun
Olorun toda awon oke igba ni
eyin ni mo fi ope mifun
tani hun o tun gbe ga o
bikon shey baba loke
tani hun o tun fi gbogbo ope mi fun
olorun toda awon oke igbani o
eyin ni mofi ope mi fun
tani hun o tun gbe ga o
bikon shey baba loke
tani hun o tun fi gbogbo ope mi fun oooo
olorun toda awonnnnn
oke igbani, eyin ni mo fi ope mi fun oooo
oluwa, eyin ni mo fi ope mi fun
eyin nikan soso (aseda aye ati orun)
eyin ni mo fi ope mi fun
eyin ma ni baba o
eyin ni mo fi ope mi fun ooo



Credits
Writer(s): Damilola & Bekes
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link