Igbowo Eda

Alagbawi mi onigbọwọ to yọ mi loko iya o
Alagbawi mi onigbọwọ to yọ mi l'okun
Modupe, ose, to san igbese mi
Modupe, ose, to san gbese mi
Iwo lo yo mi loko iya ti mo ko ori mi bo
Àní iwo lo yomi ninu oko oshi ti mo kese mi bo
Ose, modupe, to san igbese mi
Ose oo, modupe, to san gbese mi

Alagba wi mi (alagba wi mi)
Onigbọwọ eda (onigbọwọ mi)
Oseun, to san gbese mi (ose oo)
Ọpẹ ni mo wa du nitemi (alagbawi mi, onigbọwọ mi o ṣeun to san igbese mi)
Orun yo tori mi
Mo d'ominira a tu mi silẹ
Emi aji gbese ojosi
Agbelebu tu mi sile oo
Eleso ajeku, oti ko gba wole
Eleso ajeku, oti ko igba wole (kogaba wole ko)
Alagbawi mi, onigbọwọ mi
Oseun to san gbese mi
Alagbawi mi, onigbọwọ mi
Oseun to san gbese mi

Iyan ki s'ẹgbẹ isu laye
Ma fo tolori we panduku
Ibi isubu yato si ibi idide
Ogba edeni lakoba ti wa
A tun ipin ẹda yan lati ibi agbari
A tori aye se ni calvary
Agbelebu ibi ifese jin
A ká iboju kuro aso ipọnju faya
Alapa pe oniya ji oju re mo
Ko je ni fi ni korogodo
Alapa pe ti kogba wole

Alagbawi mi (ose Olodumare)
Onigbọwọ mi (alagbawi onigbọwọ mi)
Ose, to san igbese mi (ose ooooo)
Alagbawi wi mi (alagbawi mi)
Onigbọwọ mi (onigbọwọ eda)
Ose, to san igbese mi

Akọsilẹ gbese ti parẹ
Kosi wulo afi jo ko mo
Ajigbese bo logun a sin gba
Ẹjẹ ra jí gbese ateni dogo
Eniti a dẹni tin fonka
Eku ibanuje wa di erin
Ajigbese ati adogo a ti bo
Igi ti da okun ti ja
Awa ti yọ
Eni to wo igi ohun lo ri iye
Ominira ti de

Alagbawi mi (ata dogo)
Onigbọwọ mi (atoni gbese)
Ose, to san gbese mi (ata ji gbese awa mẹtẹta)
Alagbawi mi (la ba bo loko iya o)
Onigbọwọ mi (laba bo loko eru)
Ose, to san gbese mi (opelope onigbọwọ alagbawi eda oo)

Ọpẹ onife alailẹgbẹ
F'ogo folugbala t'ojoko nite anu
Ọpẹ alagbawi igbọwọ eda oo
Owaye wa fi iku agbekorun mi tẹlẹ jona
O ko mi ni la iya to ni Kọla aye o le ko o
Emi mimo wa di ogun ibi si iye fún emi
Mo d'ominira ah ah mo do mo
Mo d'ominira eh eh moyege
Baba mi lo laye at'ọrun, mo d'ominira
Mo d'ominira eh eh, moyege
Mo d'ominira ah ah, mo d'omo (mo di ọmọ lat'oni lọ)
Mo d'ominira eh eh, mo yege (sha rẹni to sọbẹ pẹlu emi)
Mo d'ominira ah ah, mo d'omo (bẹẹni ọmọ ni mi)
Mo d'ominira eh eh, mo yege (kò sí gbese lọrùn mi ẹjẹ lo san gbogbo rẹ)

Jesu san gbese mi tan, mo bọ lọwọ aninilara
Alagbawi san tan mo dẹni aponle mo d'omo, mo d'omo mo d'ominira oooo
Mo yege mo jo'gun aye raye (mo jo'gun aye raye iye ni temi)
Mo d'omo, mo d'omo, mo d'ominira oooo
Mo yege, mo jo'gun aye raye

Mo d'ominira ah ah, mo d'omo
Mo d'ominira eh eh, moyege (alagbawi lo sa sepe Ise Aye mi)
Mo d'ominira ah ah, mo d'omo (onigbọwọ ohun lo sa sepe Ise mi o)
Mo d'ominira eh eh, mo yege (ko sí wulo afi jogo mo o)



Credits
Writer(s): Tope Alabi
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link