Adura Mi

Eyi nikan
L'adura mi
Si Olu Aseda mi

Eyi nikan
L'adura mi
Mo ti mo ona iye yi na

Mi o ni ye'se
Mi o ni pada
Emi o ni si lo
Kododo aye ma fe mo oju mi
Ju ibi t'ayo mi wa lo

Amin
Amin
Amin
O amin oo

Eyi nikan le mi nbere
Nigba ti mo n mi
Ko na t'oluwa mu mi rin yi o
K'emi ma se amoju sonu
Kin le d'ebute ogo ayanmo
K'ogo baba ko tan de opin
Imole ko tan de opin aye
Fun oruko re nikan

(O amin o)
O amin
O amin
O amin
O amin o

Eyi l'ohun temi n bere
Anu ati abo re
Owo re at'otito re
Ko tan mi l'aye d'ogbo
Ani ko se Asa at'Apata
Ko ma yo wo ni pe ja mi
Eni sare ibi le mi
Ko f'ori ara re gbe
Gbe'be mi s'ase
O amin o

(Amin o)
O amin
O amin
O amin
O amin o
(Amin)

Eyi l'ohun temi n bere
Awon omo to fun mi
Ki won sin o
Iwo nikan
Ki won ko se rere laye
K'alaafia ati ife re
Ma joba ni ile wa
Opopona majemu ayeraye
Ni ka wa o fo titi
Alaafia ogbo tutu
Ni ipin tawa lodo aseda

(Beeni ko ri oo)
O amin
O amin
O amin
O amin o

Eyi nikan l'adura mi
Owo oluwa ko kun mi pupo
Ki ina mi jo fun isoji si
Labe asiapada bo re
Ka sa ko pada l'ohun kan
K'ero ijoba re ko po si
To ba si de oko iyawo
Awa yo ba o joba
Adura mi ni
Ko se oo

(O se O se)
O amin
O amin
O amin
O amin o

Adura mi ma ti gba
Baba mi a gbo
Ohun ti emi bere
Baba ti se oo
Ogede ki n gb'odo ko ya gan (beeni)
Baba mi a gbo
Elegbede f'owo lu'gi o dun jaye oo
Baba ti se oo

Omo o le bere akara ka fun lo kuta oo
Baba mi a gbo
Igbagbo ninu Jesu kin doju tini
Baba ti se o
Ohun gangan ti mo n bere
Baba mi a gbo
Ati iran de ran mi Olorun la o ma sin titi
Baba ti se o

Ke mi o mo fo ojo aye mi si Oluwa
Baba mi a gbo
Oore ofe ati iferan Olugbala mi si
Baba ti se o
Kin ma joko l'ese re nigba gbogbo ko eko oo
Baba mi a gbo
K'emi se yi di ojo ogbo tutu ni mo bere oo
Baba ti se o

Iran peregun won ki rin wowo kin ku dale (beeni)
Baba mi a gbo
Ka le wa san mi ju owuro lo Olu nla mo be o
Baba ti se o

(eeeh amin oo)
O amin
O amin
O amin
O amin o

Ase
Amin
Ase o
Ema s'amin ase

Amin
Amin
Ase



Credits
Writer(s): Tope Alabi
Lyrics powered by www.musixmatch.com

Link